Celebrity

Mo bá gbogbo Krìstẹ́nì, ọmọlẹ́yìn Jésù káàkiri àgbáyé yọ ayọ̀ ọdún Kérésìmesì. Ní àkókò ìrònú jin…

Mo bá gbogbo Krìstẹ́nì, ọmọlẹ́yìn Jésù káàkiri àgbáyé yọ ayọ̀ ọdún Kérésìmesì.
Ní àkókò ìrònú jinlẹ̀ àti àṣeyẹ yìí, mo rọ gbogbo mùtúmùwà, t’olórí t’elésè láti ṣe àfarawé Jésù Krístì tí à ń ṣe àjọyọ̀ rẹ̀ lónìí, ká fi ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìṣoore hàn nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ aláìní, ìpèsè oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pá àti ibùgbé fún ẹni tí kò ní ilé lórí, láì bìkítà nípa ẹ̀sìn, ẹ̀yà tàbí irúfẹ́ ẹ̀dá takọtabo.
Ẹ kú Ọdún, ẹ kú Ìyèdún. Kí Elédùà ṣọ́ gbogbo wa, bá a ti ń k’íyèsára. A ò ní bá wọn kú ikú ọ̀wọwọ̀ọ́, a ò ní f’ọjọ́ ọlọ́jọ́ lọ, l’áṣẹ Èdùmàrè.
Ọdún á y’abo fún gbogbo wa o! ÀṢẸ!

·


Source

Related Articles

28 Comments

  1. 🙏🏽🤲🏻 A seasonal greetings from Kenkswalls @ Kabiesi, Wishing him a prosperous new year in advance 🙏🏽🤲🏼

  2. Merry Christmas to HIM Adeyeye Enitan Ogunwusi and happy new year in advance long reigns on the throne the blessed King.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button